Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àṣírí ikú tó pa Bàba Sùwé, gbajúgbajà adẹ́rinpòṣónú nnì? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 23, 2021

Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àṣírí ikú tó pa Bàba Sùwé, gbajúgbajà adẹ́rinpòṣónú nnì?


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajubaja adẹrinpoṣonu nni, Ọgbẹni Babatunde Omidina, ẹni ti ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye mọ si Baba Suwe ti jade laye.
 
Baba Suwe jade laye lọjọ Aje, Mọnde ana, lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

Latigba ti agba oṣere adẹrinpoṣonu naa ti ku ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.
 
Aisan kan ti wọn lo n ba Baba Suwe finra lati ọdun 2011, iyẹn lẹyin to jade kuro lahamọ awọn ajọ to n ri sọro gbigbe oogun oloro, iyẹn National Drug and Law Enforcement Agency ni wọn loo pada gba ẹmi rẹ.
 
Bẹ o ba gbagbe, iroyin ọhun jade ni nnkan bi oṣi kẹwaa, ọdun 2011 wi pe ajọ NDLEA mu Baba Suwe fun wi pe o gbe egboogi oloro, ti wọn si daa duro fun bi ọsẹ meji gbako, ṣugbọn ti wọn ko ri ohunkohun lara rẹ.
 

Latigba yii la gbọ pe aisan ti wa lara Baba Suwe, ti ko si fi bẹẹ ri owo lati tọju ara rẹ. Ni nnkan bi ọdun meji sẹyin la gbọ pe Baba Suwe lọ gba itọju nilu Oyinbo, to si jẹ pe latigba to ti de ni nnkan ko ti lọ deedee fun mọ, eyi to jẹ ko pa iṣẹ tiata ti.

Bi Baba Suwe ṣe jade laye, ni ọmọ rẹ, Adeṣọla ti gbe e sori ikanni ayelujara ti Instagiraamu rẹ wi pe awọn mọlẹbi, awọn aṣere tiata ati ijọba Naijiria kọ lati ṣe iranlọwọ fun baba oun, ko to di pe o jade laye, to si loun yoo gbe igbesẹ lee lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI