Adéṣọlá, ọmọ Bàba Sùwé ti bẹ̀bẹ̀, 'kò sẹ́ni tó gbàgbé bàbá mí sórí àìsàn' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 23, 2021

Adéṣọlá, ọmọ Bàba Sùwé ti bẹ̀bẹ̀, 'kò sẹ́ni tó gbàgbé bàbá mí sórí àìsàn'


Adeṣọla Omidina, ọkan lara awọn ọmọ ti Baba Suwe fi silẹ saye lọ ti rawọ si ẹgbẹ awọn oṣere tiata ti Theatre Arts And Motion Pictures Practitioners Association Of Nigeria, iyẹn TAMPAN, awọn oṣere, ati gbogbo ọmọ Naijiria lapaọ lati forijin oun, pẹlu aṣiṣe toun ṣe nipa fọnran toun gbe jade lati fi tabuku ba gbogbo wọn.
 
Ni kete ti Baba Suwe jade laye ni Adeṣọla gbe fọnran oun pẹlu oku baba rẹ sita, nibi to ti n fẹsun kan ẹgbẹ oṣere tiata, awọn oṣere tiata, ati mọlẹbi, to fi mọ gbogbo ọmọ Naijiria wi pe wọn ko odide iranlọwọ.
 
Adeṣọla sọ pe ọpọ igba lawọn pariwo sita wi pe Baba oun nilo iranlọwọ, ṣugbọn ti ko sẹni to dide iranlọwọ naa, iyẹn nigba to wa lori idubulẹ aisan.
 
Ṣugbọn nigba to n bẹbẹ fun aṣiṣe naa, Adeṣọla sọ pe "Gẹgẹ bi ọmọ agba oṣere tiata nni, Oloogbe Babatunde Omidina ‘Baba Suwe’, mo n fi tọkan-tọkan gbe ọrọ yii sita lati ko ọrọ mi jẹ lori fọnran ti mọ gbe jade nipa iku Baba Suwe pẹlu aṣiṣe.
 
"Ẹgbẹ oṣere tiata ti Nollywood, TAMPAN, ijọba, awọn Wolii, ẹbi ati ololufẹ dide iranlọwọ lọna ti wọn mọ. Mo n bẹ gbogbo ẹgbẹ, eeyan ati mọlẹbi ti ọrọ mi ba wi wi pe ki wọn forijin mi. Lẹẹkan si, ẹ ma ṣe gba fọnran naa to n kaakiri ori ayelujara gbọ mọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI