Olóyè Adérìnókùn kẹ́dun ikú Amosu, alága ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 14, 2021

Olóyè Adérìnókùn kẹ́dun ikú Amosu, alága ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn l'Ógùn


Akinruyiwa tilu Owu, Oloye Olumide Aderinokun ti ba gbogbo ẹgbẹ akọroyin kaakiri ipinlẹ Ogun kẹdun iku alaga wọn, Kọmureedi Olusọji Samson Amosu to jade laye lonii, ọjọ Aiku, Sannde.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Oloye Aderinokun gbe jade lati fi ba wọn kẹdun, lo ti sọ pe adanu nla niku naa jẹ, nitori pe ojiji lo jẹ.

Bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun fun mọlẹbi, ọrẹ ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ akọroyin ni ọkan lati le ni imumọra ipapoda alaga wọn to doloogbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI