Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tó n kó ìbásùn fọ́mọ ọdún méjìlá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 22, 2021

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tó n kó ìbásùn fọ́mọ ọdún méjìlá


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ olukọ fasiti Alex Ekwueme Federal University to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, lori ẹsun wi pe o n fipa ba ọmọ ọdun mejila kan to jẹ ọmọ ẹni to n ba ṣi geeti ile rẹ laṣepọ karakara.

Ọjọgbọn Felix Anyaegbunam ni wọn pe orukọ olukọ fasiti ọhun, ti wọn si ni lati nnkan bi oṣu mẹfa sẹyin lo ti n fipa ba ọmọ naa laṣepọ nikọkọ, tẹnikẹni ko si mọ sii.

Alaga ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan, HURIDE, Ọgbẹni Sampson Oko Nweke, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si ni Ọjọgbọn naa ti wa lahamọ, nibi to ti n sọ ohun to ri lọbẹ to fi n waaru ọwọ.

Bakan naa ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi, Arabinrin Loveth Odah, sọ pe kọmiṣanna awọn, Aliyu Garba, ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ, ki wọn si le ri ojutu ọrọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI