Nítorí òpópónà tíjọba Kwara ṣe gba ilé Akọgun Oyedepo, àwọn aráàlú gbóṣùbà fún gómìnà wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 22, 2021

Nítorí òpópónà tíjọba Kwara ṣe gba ilé Akọgun Oyedepo, àwọn aráàlú gbóṣùbà fún gómìnà wọn


Gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara ni wọn ti n gbe oṣuba kare fun gomina wọn, Adbdulrahman Abdulrazaq, lori bo ṣe bu ọwọ lu iwe aṣẹ wi pe ki wọn ṣe opopona kọja niwaju ile Akọgun Iyiọla Oyedepo.

 
Ikorita Overcomers to wa lagbegbe Government Day Secondary School, iyẹn loju ọna fasiti, ipinlẹ naa la gbọ pe opopona naa wa, ti wọn si ni ipo to wa ko yẹ ilu to n sare ni idagbasoke rara, idi ree ti wọn ni gomina fi bu ọwọ lu fun ṣiṣe.
 
A gbọ pe fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin lawọn ijọba to ti kọja lọ ti pa opopona yii ti, ti wọn ko si ṣe ohunkohun sii, eyi to jẹ kawọn ara agbegbe ọhun maa wa ninu inira igbokegbodo ọkọ.
 
Ṣugbọn ni bayii, ijọba ti sọ pe atunṣẹ opopona yii yoo pari laipẹ, ti yoo si mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ ati eto ọrọ aje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI