Wọ́n ní ìgbésẹ̀ ìpàdé àlàáfíà tí Fágbèmí n ṣe káàkiri nínú APC ti n kó ìdààmú bá Sàràkí àti PDP ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 24, 2021

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ ìpàdé àlàáfíà tí Fágbèmí n ṣe káàkiri nínú APC ti n kó ìdààmú bá Sàràkí àti PDP ní Kwara


Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti fidi rẹ mulẹ wi pe ọkan olori ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinklẹ Kwara, Sẹnetọ Bukọla Saraki ko balẹ mọ rara bayii, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ ọhun ti bẹrẹ ipade alaafia laaarin awọn agbaagba ẹgbẹ.
 
Kii ṣe eyi nikan, AWIKONKO gbọ ipade alaafia ọhun ti Fagbemi n ṣe bayii lo ni atilẹyin awọn agbaagba ẹgbẹ APC bii Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati alaga ẹgbẹ APC akọkọ, Oloye Bisi Akande ninu.

Ohun ti a gbọ bayii ni pe ọkan awọn oloye ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa ko balẹ mọ rara bayii, pẹlu bi wọn ṣe rii pe alaafia ti n jọba gidi ninu APC kọja sisọ, eyi ti ko tun ni jẹ ki wọn rọwọ mu ninu idibo ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI