AbdulRazaq ti ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Sẹnetọ Olóríẹgbẹ ti màmá rẹ̀ jáde láyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 12, 2021

AbdulRazaq ti ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Sẹnetọ Olóríẹgbẹ ti màmá rẹ̀ jáde láyé


Lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo ibanikẹdun si Sẹnetọ Ibrahim Yahya Oloriẹgbẹ, to n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ Kwara (Kwara Central) nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lori iku mama rẹ, Alaaja Fatimah Maronike Oloriẹgbẹ.

Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹjọ, oṣu yii la gbọ pe Alaaja Fatimah Oloriẹgbẹ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Iya Funtua jade laye.

Ṣaaju asiko yii Gomina AbdulRazaq ti kọkọ fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si Sẹnetọ Olóríẹgbẹ nipa iku mama naa, ẹni to ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akikanju to fi gbogbo aye rẹ jin fun Allah.

Lara awọn to kọwọ rin pẹlu Gomina AbdulRazaq ni Gomina ipinlẹ Bornu, Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum; Sẹnetọ Ali Ndume; ati alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ ofin eto ayika (Kwara State Environmental Task Force) Alaaji Abdulrazaq Jiddah.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI