Wòlíì Ayọ̀délé fèẹ́ ró àwọn opó àti arúgbó lágbára l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 12, 2021

Wòlíì Ayọ̀délé fèẹ́ ró àwọn opó àti arúgbó lágbára l'Ékòó


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun Wolii agbaye nni, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, ẹni to jẹ alaṣẹ, apaṣẹ ati oludari ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, lati ro awọn opó arugbo lagbara ninu oṣu keji ọdun to n bọ, iyẹn 2022.

Nibi ayẹyẹ iain idupẹ ọlọdọọdun ti Wolii Ayọdele maa n ṣe la gbọ pe o ti fẹẹ lo anfaani rẹ lati ro awọn opó ati arugbo naa lagbara.

Lara awọn nnkan ti a gbọ pe Wolii Ayọdele fẹẹ fi ṣe iranlọwọ fun wọn ni fifun ẹnikọọkan wọn ni owo, owo ile, ounjẹ ati oniruuru ẹbun miran ti yoo ṣe lanfaani.

Kii ṣe akọkọ ree ti Wolii Ayọdele yoo maa ṣe iranlọwọ fawọn eeyan lọdọọdun, paapaa loorekoore, nipasẹ ajọ alaanu rẹ, ṣugbọn eyi to fẹẹ waye lọdun to n bọ naa fẹẹ gbọna ara yọ lakọtun.

Awọn opo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa la gbọ pe Wolii Ayọdele ti ṣe iranlọwọ fun latigba to ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI