Adérìnókùn bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Dàpọ̀ Abíọ́dún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 22, 2021

Adérìnókùn bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Dàpọ̀ Abíọ́dún


Akinruyiwa tilu Owu nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, Olumide Aderinokun ti bu ẹnu atẹ ijọba Dapọ Abiọdun nipinlẹ naa, to si ni ko dide lati kora giri iṣakoso to n ṣe.
 
O ni awọn ọmọ ipinlẹ Ogun n fẹ ri ipa rere ti Gomina Abiọdun n ko lawujọ, paapaa lẹka eto idagbasoke to ṣe pataki sawọn araalu, eyi to ni Abiọdun ko gbajumọ.
 
Aderinokun sọ peko si idagbasoke kan ṣoṣo ti Gomina Abiọdun le ri tọka si, to yatọ si ti awọn opopona to n ṣe, eyi to jẹ pe ọwọ yọbọkẹ ni wọn fi n mu awọn opopona ọhun, ati pe awọn akanṣe iṣẹ ti araalu yoo mọ riri wọn ni wọn n fẹ.

Ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ogun naa tun tẹnumọ ọrọ rẹ wi pe awọn opopona ti Dapọ Abiọdun loun n ṣe lo ti n kọja ọjọ to yẹ ki wọn ti pari rẹ, ati pe iṣẹ opopona ṣiṣẹ kii ṣe iṣẹ to n gba ọdun gbọgbọrọ bi eyi toun n ṣe yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI