AbdulRazaq gbé 'bọ́jẹ̀ẹ̀tì ìtèsíwájú ìdàgbàsókè' ọdún 2022 lọ sílé ìgbìmọ aṣòfin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 23, 2021

AbdulRazaq gbé 'bọ́jẹ̀ẹ̀tì ìtèsíwájú ìdàgbàsókè' ọdún 2022 lọ sílé ìgbìmọ aṣòfin


Lonii, Ọjọru, Wẹsidee ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara gbe bọjẹẹti itẹsiwaju lati pari awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ kaakiri agbaye ati igberiko ipinlẹ naa.
 
Bọjẹẹti ọhun to jẹ biliọnu N189.4b naira ni wọn yoo ti lo ida marunlelaadọta le ni mẹta (55.3per cent) lati fi ṣe awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ pari kaakiri ipinlẹ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe ida mejila ataabọ (12.5per cent) ni bọjẹẹti yii fi le si tọdun 2021 ti a ṣẹṣẹ n lo pari yii.
 
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq sọ pe “Bọjẹẹti ọdun 2022 ti a  gbe wa siwaju ile igbimọ aṣofin lonii, la gbe kalẹ lati fi tẹsiwaju awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ. Eyi lo jẹ ka pe e ni Bọjẹẹti Itẹsiwaju Awọn Ayipada Idagbasoke Rere.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI