Àsìkò ti tó fáwọn ọmọ Yorùbá láti já ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn alátẹnujẹ àgba Yorùbá - Ẹgbẹ́ OPC pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 16, 2021

Àsìkò ti tó fáwọn ọmọ Yorùbá láti já ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn alátẹnujẹ àgba Yorùbá - Ẹgbẹ́ OPC pariwo síta


Ẹgbẹ ajijangbara ilẹ Yoruba, iyẹn Oodua People's Congress, OPC ti sọ ọ sita gbangba wi pe inu awọn ọmọ orilẹ-ede yii ko dun sawọn alaṣẹ ati alakoso orilẹ-ede yii, paapaa bi wọn ṣe dori eto ọrọ aje kodo.
 
Razaq Arogundade to jẹ Aarẹ ẹgbẹ naa lo sọrọ naa nibi ayẹyẹ ọdun Ogun Ajọbọ to waye ninu ọgba ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ti Ansar-Ud-Deen, eyi to wa lagbegbe Makun nilu Ṣagamu lọjọ kẹtala si ọjọ kẹrinla, oṣu yii.
 
Arogundade sọ pe ijọba orilẹ-ede yii ati gbogbo awọn ti wọn dibo yan sipo oṣelu lorilẹ-ede yii ti kuna patapata pẹlu bi wọn ṣe jẹ ki eto ọrọ aje dẹnukọlẹ, to si ti bajẹ kọja afẹnuroyin, eyi to lo jẹ ki orilẹ-ede bii Venezuela ati Zimbabwe maa lewaju wa.
 
O tun sọ siwaju ninu ọrọ rẹ wi pe yatọ si pe ijọba kuna lẹka eto ọrọ aje, o ni wọn tun kuna lẹka eto aabo, ti awọn eeyan ko le sun asundọkan, tawọn eeyan ko si le lọ si ibiṣẹ lai wa ni ibẹrubojo.
 
Bakan naa lo tẹsiwaju pe ohun kan ṣoṣo ti awọn ọmọ orilẹ-ede yii le fọwọ sọya fun labẹ ijọba Ọgagun Muhammadu Buhari ni abamọ, ijinigbe, iṣekupani awọn agbebọn, wahala awọn Fulani darandaran, ebi, ọwọgogo ounjẹ ati oniruuru ajalu.
 
O ni o jẹ ohun ibanujẹ wi pe nigba tawọn Fulani n wa gbogbo ọna lati jẹ ki orilẹ-ede yii di tiwọn, ṣe ni awọn agba Yoruba naa tun n wa ọna lati ta wa danu fun ti ara wọn nikan, lai wo ti awọn mẹkunnu.
 
Siwaju sii lo ṣapejuwe awọn agba Yoruba gẹgẹ onimọ-tara-ẹni nikan, alajẹbanu ti kii boju wẹyin, ti wọn n fiya jẹ awọn eeyan lọna aitọ.
 
Arogundade sọ pe asiko ti to fun awọn ọmọ Yoruba lati ja ara wọn gba kuro lọwọ awọn adari alatẹnujẹ agba Yoruba, to jẹ pe ti ara wọn nikan ni wọn mọ.
 
Lakotan, Arogundade gbawọn ọdọ lamọran lati yee ṣẹgbẹ okunkun to n fojoojumọ da ẹmi wọn legbodo, to si ni aṣiwaju ọjọ iwaju rere lo yẹ ki wọn jẹ fun ara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI