KWARTMA fọkàn àwọn aráàlú balẹ̀ lórí ìgbòkègbodò ọkọ́ lásìko ọdún Kérésìmesì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 16, 2021

KWARTMA fọkàn àwọn aráàlú balẹ̀ lórí ìgbòkègbodò ọkọ́ lásìko ọdún Kérésìmesì


Bi ayẹyẹ ati pọpọṣinṣin ọdun Keresimesi ṣe n sunmọ etile, ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Kwara, KWATMA ti sọ pe gbogbo eto lo ti pari patapata, ati pe awọn ti ko awọn ẹṣọ aabo oju popona wọn ti ko din ni igba ati aadọta, 250 sita.
 
Alakoso ileeṣẹ naa, Alaaji Yekeen ‘Tunde Bello lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, to si ni gbogbo awọn agbegbe ati opopona ti sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti maa n waye ni wọn yoo ti ṣiṣẹ.
 
'Tunde Bello sọ pe kii ṣe tuntun mọ pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ maa n waye lawọn akoko ọdun bii iru eyi to n bọ lọna yii, ṣugbọn to sọ pe ko nii si iru rẹ mọ lakooko yii, nitori pe awọn ti da awọn oṣiṣẹ wọn sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI