Atiku, Tinubu kò níbi tí wọ́n n lọ nínú ìdìbò ọdún 2023- Wòlíì Ayọ̀délé ju bọ́mbù àsọtẹlẹ síta o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 22, 2021

Atiku, Tinubu kò níbi tí wọ́n n lọ nínú ìdìbò ọdún 2023- Wòlíì Ayọ̀délé ju bọ́mbù àsọtẹlẹ síta o


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati oludije sipo aarẹ lọdun 2019, Alaaji Atiku Abubakar ko nibi ti wọn n lọ ninu idibo apapọ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023

Wolii Ayọdele lo sọ eyi nibi akanṣe eto àsọtẹlẹ ọlọdọọdun to maa n waye ninu ijọ rẹ, eyi to waye lonii, Ọjọru, Wẹsidee.

O ni pupọ awọn agba oloṣelu tawọn eeyan n wo loju lati du ipo Aarẹ ni wọn ko nii lanfaani lati du ipo naa, ati pe pupọ wọn ni ko nii ri tikẹẹti gba.

Bakan naa lo tun mẹnuba awọn oludije to dara fun ipo Aarẹ, to si ni gbogbo wọn ni yoo ṣe daradara bi wọn ba jade du ipo ọhun.

Wolii Ayọdele sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu APC ba fun Tinubu ni tikẹẹti lati jade du ipo Aarẹ, yoo kuna nipinlẹ Eko, nitori pe PDP ni yoo wọle l'Ekoo, ati pe Tinubu yoo padanu ipp Aarẹ.

Agba Wolii naa tiẹ tun fi kun ọrọ rẹ wi pe yoo wu ẹgbẹ APC lati fun Tinubu ni tikẹẹti ipo Aarẹ, ki ẹgbẹ naa le padanu.

O tẹsiwaju pe igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ko nii wọle gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ APC.

Nigba to n sọrọ lori awọn ti yoo ṣe daadaa fun ipo Aarẹ ati igbakeji Aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Wolii Ayọdele sọ pe awọn bii Babatunde Faṣọla, Rotimi Amaechi, Kayọde Fayẹmi, Rauf Arẹgbẹṣọla, Babagana Zulum

Fun ti PDP, o lawọn bii Aminu Tambuwal , Bukọla Saraki, Ṣeyi Makinde, Bala Mohammed ati Rabiu Kwankwaso yoo tayọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI