Lẹ́yìn tó sọ fún màma rẹ̀ wí pé òun fẹ́ẹ́ lọ kọ́ iṣẹ́ 'Yahoo', àwọn ọmọ 'Yahoo' fi ọmọ ogún ọdún ṣòògùn owó l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 22, 2021

Lẹ́yìn tó sọ fún màma rẹ̀ wí pé òun fẹ́ẹ́ lọ kọ́ iṣẹ́ 'Yahoo', àwọn ọmọ 'Yahoo' fi ọmọ ogún ọdún ṣòògùn owó l'Abẹ́òkúta


...Colorado lo mu ku - Awọn ọmọ Yahoo jẹwọ
 
Ọrọ buruku toun tẹrin-in nigba ti wọn sọ pe gendekunrin, ọmọ ogun ọdun kan, Alexander Uzoma dagbere fun mama rẹ wi pe oun fẹẹ lọ kọ iṣẹ 'Yahoo-Yahoo', ki owo le maa wọle sapo oun daadaa, ṣugbọn to jẹ pe ibi to ti lọ kọ iṣẹ naa ni wọn ti pa a danu lati fi ṣoogun owo.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii ni Uzoma dagbere fun mama rẹ, Ogechi Alexander wi pe oun fẹẹ lọ kọ iṣẹ jibiti ori ayelujara lọdọ awọn ọrẹ oun, ṣugbọn to jẹ wọn ko ri apadabọ rẹ latigba naa.
 
Nigba ti wọn sọ pe wọn ko ri Uzoma, lo mu ki mama rẹ, Ogechi gba teṣan ọlọpaa to wa lagbegbe Adigbe nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọ lati fi to wọn leti wi pe oun ko ri ọmọ oun, ati pe oun pe foonu rẹ titi, ko lọ.
 
Igba ti wọn rii pe iṣẹ iwadii naa ko fi bẹẹ fẹsẹ rinlẹ to, lo mu ki awọn ọbi Uzoma gba olu ileeṣẹ ọlọpaa lọ lati lọ fi to wọn leti, iyẹn ni ẹka kan ti wọn pe ni Modud Operandi.
 
Ninu iwadii ti wọn ṣe nibẹ ni wọn ti gbọ pe ẹnikan ti wọn ri pẹlu Uzoma gbẹyin ni Babatunde Owoṣeni, ti wọn si lọ gbe e lati fọrọ wa lẹnu wo.
 
Babatunde lo pada jẹwọ wi pe oun nikan kọ loun mọ nipa bi Uzoma ṣe ku, ati pe awọn tawọn jọ n ṣiṣẹ wa nile. Eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa lọ ko awọn miran ti wọn pe ni Azeez Oyebanji, iyẹn Biggy; Ayọbami Adeṣina ati Balogun Sulaiman.
 
Awọn mẹta yii lo pada jẹwọ pe lotitọ ni Uzoma wa sile awọn lati kọ iṣẹ Yahoo, ati pe ọjọ to de lawọn ṣe faaji, tawọn si mu egboogi oloro kan ti wọn n pe ni Kolorado {Colorado}, ko to di pe awọn gbagbe sun lọ.
 
Wọn jẹwọ siwaju pe nigba tawọn maa pada laju ni nnkan bi agogo mẹjọ alẹ, awọn ti rii pe Uzoma ti dakẹ, lẹyin to ti bi gbogbo nnkan to jẹ.
 
Wọn jẹ ko di mimọ pe nigba tawọn ko mọ bi wọn yoo ṣe oku rẹ, lo jẹ ki wọn lọ ju oku rẹ sori afara Kuto, ki ijọba le gbe e.
 
Ninu ọrọ wọn ni wọn ti sọ pe Biggy lo daba kawọn lọ ju oku rẹ sọnu, eyi to mu ki Ayọmide ati Gafar ranṣẹ pe awakọ kan ti wọn lo lati ju oku rẹ sọnu.
 
Awọn oṣiṣẹ eto ilera nipinlẹ Ogun lo pada gbe oku naa lati sin, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ati pe iwadii fidi rẹ mulẹ wi pe ṣe ni wọn la nnkan mọ Uzoma lori to fi ku.
 
Iwadii awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ wi pe Aafa kan nilu Ijẹbu mọ nipa bi wọn ṣe pa Uzoma, ṣugbọn ti aafa naa pada sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa rẹ, ati pe ọtọ ni eto adura toun ṣe fun wọn.

Ju gbogbo rẹ lọ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lẹkunrẹrẹ lati mọ iru iku to pa Uzoma, ko to di pe wọn foju gbogbo awọn tọrọ kan ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI