Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, lawọn eeyan n gbera wọn ṣanlẹ lopin ọsẹ to kọja yii, nigba ti ọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Wezzie Msiska padanu ẹmi rẹ sinu ijamba mọto lọjọ igbeyawo rẹ.
A gbọ pe oju ọna sibi gbagede ti wọn ti ayẹyẹ igbeyawo naa ti fẹẹ waye ni Wezzie wa ko to pade iku ojiji, eyi to ko awọn eeyan sinu wahala ati idaamu, to si sọ ọjọ naa di ọjọ ẹkun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, orilẹ-ede Malawi niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun 2021.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣe ni wọn lọ gbe Wezzie nile ẹ, ti wọn si n gbe e lọ si ṣọọṣi ti wọn ti fẹẹ so oun ati ololufẹ rẹ, Victor Kayera papọ, ko to di pe mọto Nissan Xtera kan lọ kọlu wọn lojiji.
Ojiji ti mọto ọhun kọlu wọn lo mu ki Wezzie fori gba, to si gbagbẹ sọda sọrun alakeji. Awọn ẹlẹyin aanu to wa nibẹ la gbọ pe wọn sare gbe Wezzie lọ si ọsibitu Kasungu DHO lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti wọn sọ pe ẹpa ko boro mọ.
Ayẹwo ti wọn lawọn dokita fun un fidi mulẹ wi pe ẹja ti n da ni ara rẹ lati inu, iyẹn internal bleeding, eyi gan-an lo ṣeku pa a.
No comments:
Post a Comment