Lẹ́yìn tí wọ́n peregedé ní Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Kwara fẹ́ẹ́ ṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lágbayé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 20, 2021

Lẹ́yìn tí wọ́n peregedé ní Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Kwara fẹ́ẹ́ ṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lágbayé


Lọsẹ to kọja yii ni awọn akẹkọọ ipinlẹ Kwara fi itan tuntun balẹ fun ipinlẹ naa, pẹlu bi wọn ṣe gba ipo kin-in-ni nibi ti ifigagbaga ile-ẹkọ ti aarẹ, iyẹn President's School Debate.
 
AWIKONKO gbọ pe latigba idijẹ naa ti bẹrẹ, ipinlẹ Kwara ko gba ipo kin-in-ni ri, ṣugbọn ti wọn pada tayọ kọja afẹnusọ lọdun yii.
 
Idije 2021 National Presidential Inter Basic Schools Debate lo waye laipẹ yii laaarin awọn akẹkọọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria, eyi ti ipinlẹ Kwara naa wa lara wọn.
 
 
 
Bi wọn ṣe gbegba oroke ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fun gbogbo awọn akẹkọọ ipinlẹ naa to kopa patapata ni eto ẹkọ ọfẹ lati ipele ti wọn wa, titi ti wọn yoo fi jade ile-ẹkọ giga to ba wu wọn lati lọ. 
 
Ni bayii, iroyin tuntun to ṣẹṣẹ tẹ wa lọwọ ti sọ pe awọn akẹkọọ yii naa ni wọn yoo lọ ṣoju orilẹ-ede Naijiria lagbaye, nibi idijẹ imọ-ẹkọ agbaye lọdun to n bọ, iyẹn 2022 World Schools Debate Competition.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI