Ayé ò! Wọ́n pa Kábíyèsí danù, wọ́n tún ju òkú rẹ̀ sáàrin ọjà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 10, 2021

Ayé ò! Wọ́n pa Kábíyèsí danù, wọ́n tún ju òkú rẹ̀ sáàrin ọjà


Awọn agbebọn kan ti ṣeku pa ọba ilu Atta to wa nijọba ibilẹ Njaba, ipinlẹ Imo, Edwin Azike danu, wọn si tun lọ ju oku rẹ saarin ọja ilu lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe o ti ku.

Oni, ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe awọn araalu ṣalabapade oku Kabiyesi naa laaarin ọja ilu, eyi to n ṣe awọn eeyan ni kayefi.

AWIKONKO gbọ pe Ọjọbọ, Tọside ana ni awọn agbebọn ji kabiyesi gbe, nibi ti wọn ti ṣeku pa awọn mẹrin miran.

Ọkan lara awọn araalu to sọrọ sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba ti awọn kofiri oku kabiyesi laaarọ kutu oni, ọjọ Ẹti, Furaidee.

Alaga ẹgbẹ awọn ọba nipinlẹ Imo, Eze Emma Okeke nigba to n sọrọ sọ pe ibanujẹ nla niku ọba naa jẹ fun wọn.

O jẹ ko di mimọ pe iwa tawọn agbebọn naa hu ku diẹ kaato, ati pe o tapa si aṣa ilẹ Igbo, nitori pe eewọ ni ki wọn pa ọba tabi olori ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI