Wahala ati idaamu lo ti de ba gbogbo awọn ọdaran, ati awọn to n gbero lati sọ ipinlẹ Kwara di ibudo ti wọn yoo ti maa da wahala silẹ bayii, pẹlu bi awọn agbofinro, iyẹn awọn oṣiṣẹ eleto aabo bii ọlọpaa, oṣiṣẹ ologun, ati DSS ṣe ti dide lati gbogun ti iwa ọdaran.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree ti awọn eleto aabo yoo maa lọ kaakiri lati wa gbogbo ahere to ṣee ṣe kawọn ọdaran farapamọ si.
Ijọba ibilẹ Guusu Kwara la gbọ pe awọn eleto aabo ọhun ti ṣiṣẹ lọsẹ yii, ti wọn si wọnu inu awọn igbo ti wọn lero wipe awọn oniṣẹ ibi le sapamọ si.
Diẹ ree lara bi eto aabo ọhun ṣe lọ si.
No comments:
Post a Comment