Gbogbo agbegbe ati igberiko nipinlẹ Kwara ni yoo ni imọlara idagbasoke - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 9, 2021

Gbogbo agbegbe ati igberiko nipinlẹ Kwara ni yoo ni imọlara idagbasoke - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'Ọjọru, Wẹsidee ana ti sọ pe ko si eyikeyi ninu awọn agbegbe ati igberiko nipinlẹ Kwara ti ijọba oun yoo gboju foda ninu akanṣe iṣẹ idagbasoke, ati pe wọn gbọdọ jẹ igbadun ijọba awaarawa.
 
O ni gbogbo awọn opopona to wọnu igberiko ni yoo di titunṣe fun igbokogbodo ọkọ fawọn agbẹ, ki eto ọrọ aje le maa lọ deedee, gẹgẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
 
Nibi akanṣe eto ti wọn ṣe fun Ọjọgbọn Luke Ẹkundayọ Ẹdungbọla, eyi to waye ni fasiti tilu Ilọrin ni gomina AbdulRazaq ti sọrọ yii jade, to si gbe oṣuba fawọn alakoso lẹka eto ẹkọ, ati paapaa lori ọna ti wọn gba gbogun ti ajakalẹ arun tita {Guinea Worm}.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI