Dàpọ̀ Abíọ́dún ní káwọn tó bá fẹ́ẹ́ jáde du ipò òṣèlú kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ nínú ìjọba rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 9, 2021

Dàpọ̀ Abíọ́dún ní káwọn tó bá fẹ́ẹ́ jáde du ipò òṣèlú kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ nínú ìjọba rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...


Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ti sọ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ abẹ rẹ to yan sipo wi pe ki eyikeyi to ba n gbero lati du ipo oṣelu lọdun 2023 tete kọwe fipo rẹ silẹ, ko to to ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 to n bọ lọna yii.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ogbẹni Kunle Somọrin fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii lo ti sọ pe ko saaye fun awọn to n gba owo oṣu labẹ iṣakoso Dapọ Abiọdun, ko si tun ni erongba lati jade du ipo oṣelu.
 
O sọ pe bi ẹni ti ko fẹ ki Gomina Abiọdun roju raaye lati ṣe ijọba rẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ ni kawọn kan maa fi erongba wọn han lati jade du ipo oṣelu, iyẹn ninu awọn ti Gomina yan sipo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI