Ìdàgbàsókè òpópónà jẹ ìjọba Kwara lógún púpọ̀ - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 29, 2021

Ìdàgbàsókè òpópónà jẹ ìjọba Kwara lógún púpọ̀ - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko si agbegbe tabi igberiko naa, ti opopona to ja geere ko nii gba ibẹ kọja, ati pe itẹsiwaju opopona ṣiṣe ko nii dawọ duro.

AbdulRazaq lo ṣe ileri yii nibi ayẹyẹ ọdun Arandun to waye laipẹ yii, nibẹ lo si tun ti jẹ ko di mimọ pe ijọba oun yoo tun tunọ gbajumọ opopona ṣiṣe, ati pe ko ni agbegbe tabi igberiko naa labẹ ipinlẹ Kwara yi ko nii jẹ anfaani idagbasoke.

Ilu Arandun lo wa labẹ ijọba ibilẹ Irẹpọdun. Nibi ayẹyẹ ti ọdun yii ni wọn tun ti lo anfaani rẹ lati ṣeto ikowojọ idaji miliọnu lati ṣe akanṣe iṣẹ idagbasoke, eyi ti wọn pe ni 'N500million Appeal Fund for Development Projects and Conferment of Chieftaincy'.

AbdulRazaq tẹsiwaju pe ijọba oun yoo tun ṣe agbeyẹwo opopona Oro si Arandun lọdun 2022, ati pe awọn ohun to ba wa nilẹ naa ni wọn yoo lo lati fi mu idagbasoke ba agbegbe naa.

Bakan naa lo gbe oriyin fun gbogbo awọn ọmọ ilu Arandun lori bi wọn ṣe gbe eto naa kalẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI