Ẹni àmúyangàn wa ni ẹ́ - IEDPU gbé òṣùbà káre fún AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 27, 2021

Ẹni àmúyangàn wa ni ẹ́ - IEDPU gbé òṣùbà káre fún AbdulRazaq


Ẹgbẹ IEDPU, iyẹn Ilorin Emirate Descendants Progressive Union ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lori awọn ayipada ati idagbasoke rere to ti mu ba ipinlẹ naa laaarin asiko perete to de ijọba.
 
Alaaji Aliyu Otta Uthman, to jẹ Aarẹ ẹgbẹ naa lo gbe oṣuba yii lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa, to si ni ipa ti Gomina AbdulRazaq ti ko lẹka eto idagbasoke ko ṣee fọwọ rọ ti sẹyin, ati pe oun gan-an lo si oju awọn araalu si igbekun ti wọn ti wa fọjọ pipẹ.
 
O ni ẹgbẹ naa, pẹlu ifọwọsowọpọ Ẹmir tilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Sulu-Gambari, lo fi ẹnu ko lati sọ pe ẹni amuyangan lagboole Ilọrin, paapaa ni gbogbo ipinlẹ Kwara ni Gomina AbdulRazaq.

Nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun, ẹlẹẹkẹrindinlọgọta iru ẹ to waye lopin ọsẹ to kọja yii, lagbegbe Geri Alimi nilu Ilọrin ni wọn ti sọrọ yii jade.

Wọn ni nnkan ko tii lọ deedee daadaa bayii ri latigba ti ẹgbẹ naa ti bẹrẹ, to si ni akooko ti AbdulRazaq de ijọba ni ayipada rere bẹrẹ sii ṣẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI