Nítorí àwọn obìnrin, ìlú Ìlọrin gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí, tó fi mọ́ Aisha, ìyàwó Ààrẹ Buhari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 7, 2021

Nítorí àwọn obìnrin, ìlú Ìlọrin gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí, tó fi mọ́ Aisha, ìyàwó Ààrẹ Buhari


Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun 2021, gọngọ yoo sọ niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi ti awọn eeyan pataki-pataki ti wọn jẹ obinrin ti fẹẹ ṣe ipade agbaye.

AWIKONKO gbọ pe ijọba ipinlẹ naa, labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ṣagbatẹru eto yii, lati mọ riri ipa tawọn obinrin n ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ ọhun, paapaa lawujọ agbaye.

Eto naa ti wọn pe akori rẹ ni "Cracking The Glass Xeiling: The Story of Kwara Women" lawọn eeyan nla-nla bii Aisha Buhari, iyawo Aarẹ Muhammadu Buhari; Olufọlakẹ AbdulRazaq, iyawo Gomina AbdulRahman AbdulRazaq; ẹgbẹ awọn iyawo gomina lorileede Naijiria; Minisita f'ọrọ awọn obinrin ati iṣẹlẹ ajalu, Dame Pauline Tallen ati Sadiya Umar Faroiq; Oludamọran pataki fun Aarẹ lori ọrọ eto ọrọ aje, Ọmọwe Sarah Jubril ati gbajugbaja oniṣowo nni, Hajia Bọla Shagaya.

Nini ipade naa ni wọn yoo ti maa sọ nipa awọn ọrọ ti nii ṣe pẹlu awọn obinrin, ipa ti wọn n ko ninu idagbasoke ipinlẹ ati lẹka eto oṣelu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Yatọ si awọn wọnyi, awọn bii adajọ agba nipinlẹ Kwara tẹlẹri, Onidajọ Raliat Elelu-Habeeb; igbakeji Giwa fasiti tilu Ilọrin tẹlẹri, Ọjọgbọn Sidikat Ijaiya; atawọn mi in.

Alakoso banki akọkọ lorileede yii nigba kan ri, Ibukun Awoṣika; Alade; Jubril; Elelu; Amina Mohammed lati ajọ iṣọkan agbaye; Sheikh Abdulrahman Ahmad, alakoso agba fun Ansaru-Ud-Deen Islamic Society of Nigeria, atawọn miran ni yoo ṣe idanilẹkọọ.

Bẹẹ ni wọn yoo tun fi aami ẹyẹ da awọn obinrin to ti ko ipa to jọju ninu idagbasoke ipinlẹ Kwara lọla.




































No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI