Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ l'Ékìtì! Kọmíṣánnà kọ̀wé fipò sílẹ̀ lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 20, 2021

Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ l'Ékìtì! Kọmíṣánnà kọ̀wé fipò sílẹ̀ lójijì


Bi ọrọ eto oṣelu ṣe n fojoojumọ gbọna ara yọ nipinlẹ Ekiti, kọmiṣanna fọrọ eto idagbasoke ati ọrọ ilu nipinlẹ naa, Bamidele Faparusi, ti kọwe fipo rẹ silẹ lojiji.
 
Ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina Kayọde Fayẹmi ti sọ pe oun ti tẹwọ gba lẹta ikọwefipo silẹ naa lọwọ Bammidele.

A gbọ pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii ni Bamidele sọ pe oun ko ṣiṣẹ sin ijọba mọ fun awọn idi to ye oun nikan.
 
Ṣaaju akoko yii ni Bamidele ti fi erongba rẹ han sita lati jade du ipo gomina lọdun to n bọ, eyi ti wọn lo pọn dandan fun un lati kọwe fi ipo silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI