Adérìnókùn ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì fáwọn ọmọdé n'ìpínlẹ̀ Ògùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 20, 2021

Adérìnókùn ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì fáwọn ọmọdé n'ìpínlẹ̀ Ògùn


Ẹsẹ ko gbero ni gbagede ọgba redio ipinlẹ Ogun, iyẹn OGBC to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku, Sannde ana nibi ti gbajugbaja oloṣelu nni, Oloye Olumide Aderinokun ti ṣagbatẹru eto ayẹyẹ ọdun Keresimesi fawọn ọmọde to le ni ẹgbẹrun kan.

Kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun (Ogun Central) la gbọ awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọjọ kan soke ni wọn jẹ anfaani yii.

Oriṣiriṣi ẹbun bii baagi ti wọn n gbe lọ sileewe, ounjẹ, awọn ẹru ileewe awọn ọmọde, iṣere ọmọde ati bẹẹbẹẹlọ lawọn ọmọde fi ṣe ifajẹ.

Baba Keresimesi da awọn ọmọde laraya, bẹẹ ni gbogbo awọn ọmọde patapata fi orin ati ere ọlọkan-o-jọkan da ara wọn laraya gidi.

Nigba to n sọrọ, Akinruyiwa tilu Owu, Oloye Aderinokun sọ pe ohun to dara ni lati maa mu inu awọn ọmọde dun, paapaa lasiko ọdun bayii, to si ni gbogbo igba loun yoo maa ṣagbatẹru bi awọn ọmọde yoo ṣe maa jẹ mudunmudun eto iṣejọba awaarawa.

Diẹ ree lara bi eto ọhun ṣe lọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI