Sunday Ìgbòho kò níbi tó n lọ, ẹ̀wọ̀n ni yóò wà títí ọdún 2022 yóò fi parí - Wòlíì Ayọ̀délé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 23, 2021

Sunday Ìgbòho kò níbi tó n lọ, ẹ̀wọ̀n ni yóò wà títí ọdún 2022 yóò fi parí - Wòlíì Ayọ̀délé


Olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele l'Ọjọru, Wẹsidee ana ti ju asọtẹlẹ iyalẹnu jade sita nipa olori ajijangbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho wi pe ẹwọn ni yoo wa tii ọdun 2022 yoo fi pari, ati pe wahala yoo bẹ silẹ laaarin oun atawọn agbẹjọro rẹ.
 
Bakan naa ni Wolii Ayọdele tun sọ pe lotitọ ni Naijiria yoo pin, ṣugbọn kii ṣe labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari, ati pe ọrọ Nnamadi Kanu ati Sunday Igboho ko le pin Naijiria.
 
Wolii Ayọdele lo sọ eyi lakooko to n sọrọ lori awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2022 ati ọjọ iwaju lorileede Naijiria, ati kaakiri agbaye, iyẹn nibi akanṣe eto asọtẹlẹ ọlọdọọdun to ti maa n gba awọn akọroyin lalejo, eyi to maa n waye ninu ṣọọṣi rẹ.
 
O tẹsiwaju pe bi Igboho ko ba ṣora, ko si paarọ agbẹjọro rẹ, ohun ajalu nla yoo ṣẹlẹ.
 
Nigba to n sọrọ, o sọ pe "Mo rii wi pe bi Igboho ko ba paarọ agbẹjọro rẹ, yoo ṣoro fun un lati ja ajaye, ko si ṣẹgun, ati pe wọn ko nii tu silẹ.

"Ohun meji lo maa ṣẹlẹ; yala wọn maa fa a lẹ ijọba Naijiria lọwọ, eyi ti ko nii dara fun un, tabi ki wọn da ẹjọ rẹ lorileede olominira benin, ko si ṣẹwọn nibẹ.

"Wahala maa ṣẹlẹ laaarin Sunday Igboho ati agbẹjọro rẹ. Bi ko ba si ṣọra, wọn ko nii fi silẹ, ati pe ijọba Naijiria yoo fẹ ki wọn gbe e wa sile lati fa a le wọn lọwọ."

O wa fi kun un wi pe Naijiria yoo pin lọjọ kan, ṣugbọn kii ṣe labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari tabi nitori ọrọ ijijangbara ti Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho n pe fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI