Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọjọ Ẹti, Furaidee, ana, ti bu ọwọ lu eto iṣuna ipinlẹ Kwara fọdun 2022 ti a wa yii, eyi ti wọn sọ pe ida mẹrindinlọgọta ninu rẹ yoo lọ sinu awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ, ati tuntun ti wọn fẹẹ dawọ le, lati pari wọn lai fi akoko ṣofo.
Eto iṣuna yii la gbọ pe o din diẹ ni biliọnu lọna igba {N189,617,487,624} naira.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara bu ọwọ lu iwe abadofin eto iṣuna ọhun, ko to di pe wọn pada gbe e lọ siwaju Gomina AbdulRazaq lati fi ontẹ tirẹ sii.
No comments:
Post a Comment