Ọdaran agbebọn meji pade iku ojiji lẹnu iṣẹ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 29, 2022

Ọdaran agbebọn meji pade iku ojiji lẹnu iṣẹ l'Ogun


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ ọga wọn, Lanre Bankọle ti jẹ ko di mimọ pe awọn ọdaran agbebọn meji ti wọn koju ija sawọn Fulani darandaran kan ninu igbo Isaala Orile, nilu Ayetoro, ipinlẹ naa.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside to kọja yii la gbọ pe awọn mejeeji naa kagbako iku ojiji lakooko ikọlu yii.
 
AWIKONKO gbọ pe nibi tawọn Fulani darandaran ti n fi maluu wọn jẹjo kaakiri lawọn ọdaran agbebọn naa ti lọ dena de wọn pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro miran.
 
Lara awọn to kofiri wọn la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, ko to di pe wọn lọ koju wọn. Bi wọn ṣe kofiri awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn ti doju ibọn kọ wọn, ti wọn si lawọn ọlọpaa ko fọrọ ọhun falẹ tawọn naa fi bẹrẹ sii dabọn bo wọn pada.
 
Nibẹ la gbọ pe ibọn ti ba meji lara wọn, ti awọn yooku si juba ehoro.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa lakooko ti wọn n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ f'AWIKONKO jẹ ko ye wa pe ọlọpaa kan, Ọmọlayọ Ọlajide padanu ẹmi rẹ lakooko ikọlu naa to waye fun ogun iṣẹju gbako, ko to di pe awọn ọdaran agbebọn naa juba ehoro.
 
Wọn ni ọkada Bajaj ni ko ni nọmba idanimọ, ibọn mẹta ọtọọtọ, foonu kekere kan, ada ati oogun abẹnugọngọ loriṣiriṣi tawọn ọdaran naa ko wa jagun ni wọn ri gba lọwọ awọn meji to pade iku ojiji yii.
 
Ọga ọlọpaa, Bankọla nigba to n ba idile ọlọpaa to pade iku ojiji naa, Ọlajide kẹdun, o ṣeleri wi pe ọwọ yoo tẹ awọn to salọ naa laipẹ, lati fi imu wọn danrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI