Àwọn tó n da ìdọ̀tí síbi tí kò yẹ n'Ílọrin yóò ru igi oyin - Ìjọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 27, 2022

Àwọn tó n da ìdọ̀tí síbi tí kò yẹ n'Ílọrin yóò ru igi oyin - Ìjọba Kwara


Orin tijọba ipinlẹ Kwara n kọ fawọn to n da ilẹ sibi ti ko tọ kaakiri ilu Ilọrin bayii ni pe 'k'ọlọmọ kilọ f'ọmọ rẹ o, ooni a ro', lori bi wọn ṣe gbe igbimọ tuntun ti yoo maa ri sọrọ awọn to n da idọti nu.

Ko si nnkan meji to jẹ ki ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbe igbimọ ẹlẹni marun-un yii dide, bi ko ṣe lati fọ ilu Ilọrin to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa mọ toni-toni.
 
A gbọ pe ko sibi ti awọn eeyan, iyẹn awọn araalu ko le da idọti si, ti wọn kii sii lojuti bi wọn ba n da idọti nu. Bi wọn ṣe n gbe idọti saaarin opopona, ni wọn n gbe e siwaju ileeṣẹ ijọba, eyi to n ba ijoba funrẹ ninu jẹ.
 
 
Alaga igbimọ naa ni wọn pe ni Air Vice Marshal Ishaq Balogun {Rtd}, ẹni ti yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ eto ayika, atawọn alẹnulọrọ lati rii pe eto yii fẹsẹ mulẹ.
 
Awọn miran to tun wa ninu igbimọ yii ni Col Kayode Umar; Navy Captain Ayodele Olowolagba; Alaaji Sa'ad Ayuba Dan-musa; ati Gabriel Towoju, toun je akọwe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI