'Messiah' tí a tí n retí tipẹ́ ni AbdulRazaq - Tówojú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 29, 2022

'Messiah' tí a tí n retí tipẹ́ ni AbdulRazaq - Tówojú


Kọmiṣanna fọrọ eto ikansira-ẹni nipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Ọlabọde George Towoju, ti sọ pe Messiah ọjọ pipẹ tawọn araalu ti n reti ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, nitori pe awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke to la oju awọn eeyan si ẹtọ wọn lo dawọ le latigba to ti de ori ipo.
 
Ọnọrebu Towoju tun gbe oṣuba kare fun bi Gomina AbdulRazaq ṣe bu ọwọ lu iwe igbega fawọn oṣiṣẹ State Universal Basic Education Board (SUBEB), ẹka tipinlẹ Kwara laipẹ yii.

Ninu ifọrọwerọ ti Ọnọrebu Towoju bawọn akọroyin ṣe nilu Ilọrin laipẹ yii lo si jẹ ko di mimọ. To si ni awọn idagbasoke ti ko ṣẹlẹ ri nipinlẹ naa ni Gomina wọn ti mu wọle, paapaa lẹka eto ẹkọ.
 
Bakan naa lo tun gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori bo ṣe bu ọwọ lu owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ bẹrẹ lati ipele keje titi de ipele kẹtadinlogun, to si ni gbogbo wọn ni wọn ti bẹrẹ sii gba owo oṣu naa bayii.

"Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti fi ara rẹ han wi pe ololufẹ araalu, paapaa gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Kwara loun jẹ, eyi si la le ri ninu ọwọ to fi mu ọrọ eto ẹkọ ati awọn oṣiṣẹ.

"Ijọba ana kuna lati san awọn owo yii lati ọdun 2013, eyi lo si fa a ti ajọ UBEC fi yọ ipinlẹ Kwara kuro lara awọn to n jẹ anfaani wọn, bii idagbasoke ileewe atawọn owo iranwọ miran.

"Inu wa dun wi pe Gomina AbdulRazaq rii daju wi pe oun san awọn owo naa, lati le maa jẹ anfaani lọdọ UBEC. Mo fẹẹ fi da yin loju pe ipinlẹ Kwara ko si nibi ti wọn maa n wa tẹlẹ mọ, wọn ti sun siwaju, bi a ba n sọrọ nipa eto ẹkọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI