Àwọn tọ́ọ̀gì kọlu ọ́fíìsì PDP l'Ékìtì, ni Fáyòṣe bá fìbínú sọ̀rọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 14, 2022

Àwọn tọ́ọ̀gì kọlu ọ́fíìsì PDP l'Ékìtì, ni Fáyòṣe bá fìbínú sọ̀rọ̀


Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu kan tawọn tọọgi ṣe si ile ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, eyi to wa lagbegbe Ajilosun nilu Ado Ekiti, ipinlẹ naa.

Ana, Ọjọbọ, Tọside la gbọ pe awọn tọọgi kan ya lọ si ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ọhun pẹlu awọn nnkan ija oloro ti wọn ko dani.

Lara awọn to fi iroyin naa to AWIKONKO leti sọ pe ori lo ko pupọ awọn to wa nibẹ lakooko ikọlu ọhun yọ, nitori pe ṣe ni onikaluku sa asala fun ẹmi ara rẹ.

Ọpọ dukia olowo iyebiye, to fi mọ awọn ẹnu ọna abawọle, ferese atawọn nnkan miran.

Nigba to n sọrọ, sọ pe a fi kawọn ileeṣẹ eleto aabo tete dide iranlọwọ, lati mu awọn oniṣẹ buruku naa balẹ, ki wọn si foju wọn, atawọn to ran wọn niṣẹ ba ile-ẹjọ.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI