Ayẹyẹ ọdún karùn-ún Ọmọ Lámúrúdu, ìpínlẹ̀ Ògùn gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí lágbayé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 6, 2022

Ayẹyẹ ọdún karùn-ún Ọmọ Lámúrúdu, ìpínlẹ̀ Ògùn gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí lágbayé


Wọn ni bi a ba da ọjọ, ọjọ a pe, bi a ba da oṣu, ọsu a ko', bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri pẹlu bi ayẹyẹ ọdun karun-un ti wọn da ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu silẹ ṣe wọle de.
 
Ọjọ Ẹti, Furaide, ọla yii ni ayẹyẹ naa yoo waye Gbọngan aafin Ọba Abdulsẹmiu Ogunjọbi Arọlagbade kin-in-ni, Olorile tilu Orile-Ifọ, ijọba ibilẹ Ifọ nipinlẹ Ogun.
 
AWIKONKO gbọ pe gbọgan ti Lukjim, iyẹn Lukjim Event Centre to wa lagbegbe Olomore nilu Abẹokuta lo yẹ ki ayẹyẹ naa ti waye tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti pada sọ pe gbọngan Aafin Ọba Olorile tilu Ifọ ni yoo ti waye, bẹrẹ lati agogo mọkanla aarọ.


Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọpọ awọn eeyan pataki-pataki lawujọ, ati kaakiri agbaye ni wọn ti wa nipinlẹ Ogun bayii nitori ayẹyẹ ọdun karun-un naa.

Nibẹ naa si ni wọn yoo ti maa ṣe ifilọlẹ ati ikojade magasiini Ọmọ Lamurudu, nibi ti iwadii ijinlẹ nipa aṣa, iṣẹṣe ati ede Yoruba pari si.

Bakan naa gbogbo awọn ololufẹ ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu ni wọn ti wa nipinlẹ Ogun bayii lati fi ifẹ han.

Fun ibeere tabi alaye lẹkunrẹrẹ, e pe 08118176021.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI