Báwọn ọmọ 'Yahoo-Yahoo' ṣe pọ̀ nìpínlẹ̀ Ògùn kò ṣẹ̀yin Gómìnà Abíọ́dún - Ògúndélé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 24, 2022

Báwọn ọmọ 'Yahoo-Yahoo' ṣe pọ̀ nìpínlẹ̀ Ògùn kò ṣẹ̀yin Gómìnà Abíọ́dún - Ògúndélé


Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun, Ọmọwe Sikirulai Ogundele ti tako Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ naa wi pe bawọn to n lu jibiti lori ayelujara ṣe pọ lasiko yii, ko ṣẹyin ẹ.

Ogundele lo sọrọ naa laipẹ yii lẹyin ipade ẹgbẹ oṣelu PDP to waye nilu Abẹokuta.

O ni bi Gomina Abiọdun ko ṣe yan awọn ọdọ sipo ninu iṣakoso rẹ, paapaa bi ko ṣe gbe eto kalẹ ti yoo wa iṣẹ fun awọn ọdọ lo fa a ti wọn fi n lu jibiti ori ayelujara.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe ipo akọkọ ni ipinlẹ Ogun wa ninu awọn to n lu jibiti ori ayelujara lorileede Naijiria.

Nigba to n sọrọ, Ogundele sọ pe o yẹ ki oju ti gomina fun iru nnkan bayii, to si gba a lamọran wi pe ko wa ọna ti yoo fi wa iṣẹ fawọn ọdọ, eyi ti ko ni jẹ ki wọn ronu nipa iwa jibiti.

Siwaju sii lo sọ pe ipo ti eto aabo wa nipinlẹ Ogun ko bojumu ti, idi ree to fi gbọdọ dide lẹyin to ṣagbekalẹ ọkọ fawọn eleto aabo OP-MESSA nilu Abẹokuta.

"Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ọwọ to ba dilẹ ni eṣu maa n ya lo. Gomina ko ṣe daadaa to fawọn ọdọ, bo tilẹ jẹ pe awa la ni fasiti to pọ ju, eyi tawọn ọdọ n kẹkọọ jade loorekoore.

"Yatọ si pe ijoba yii ko naani ọdọ, ti wọn ko si pese iṣẹ, agbekalẹ wo ni wọn tun ni ti wọn fi n ran awọn ọdọ olokoowo kekeeke lọwọ?

"Amọran mi fawọn ọdọ ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun ni pe ki wọn tubọ tẹra mọ iṣẹ wọn, nitori pe PDP ti n ṣiṣẹ lati rii daju pe wọn gba wọn silẹ kuro ninu iya ajekudorogbo yii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI