Ìjáàbù kìí ṣe dandan fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ o - AbdulRazaq ṣe ìkìlọ̀ fáwọn ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ girama - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 23, 2022

Ìjáàbù kìí ṣe dandan fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ o - AbdulRazaq ṣe ìkìlọ̀ fáwọn ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ girama


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn ọga ile-ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ naa wi pe aṣọ ibori awọn obinrin musulumi, iyẹn Ijaabu (Hijab) kii ṣe dandan fun awọn akẹkọọ.

O ni ẹni ti ibori ijaabu naa ba wu ni ko lo o, wọn ko si gbọdọ ṣe e ni kanpa fun akẹkọọ ti ko ba nifẹẹ si i.

Eyi waye latari awuyewuye to tun n jẹyọ wi pe awọn ile ẹkọ Kristẹni bii Oyun Baptist High School, Ijagbo ati St Claire’s Girls Secondary School, Offa in Oyun, and Offa Local Government Area atawọn miran gbọdọ lo ijaabu ọhun.

Lakooko to n sọrọ nibi ipade ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ, iyẹn Kwara State Teaching Service Commission nilu Ilọrin, alaga ajọ naa, Malaamu Bello Abubakar sọ pe ọna alaafia ati iṣọkan ni ijọba n gba lati gbe ẹsin larugẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ajọ Peter Amogbonjaye fi sita lẹyin ipade alaafia lati pana ọrọ ijaabu yii, eyi to waye nilu Ilọrin, o sọ pe onikaluku lo ni ẹtọ rẹ labẹ ofin, to si gba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lamọran lati jawọ ninu ọrọ to le da wahala silẹ.
 
Bakan naa lo ṣe ikilọ fun awọn ọga agba nile ẹkọ girama lagbegbe Oyun wi pe ki wọn jawọ lati maa fi ipa mu awọn akẹkọọ lati wọ ijaabu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI