Ẹgbẹrun mẹtalelogun ni mo ta Kẹkẹ Maruwa ti wọn fi ṣe mi laanu danu, mi o mọ pe aṣiri maa tu - Azeez Saka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 29, 2022

Ẹgbẹrun mẹtalelogun ni mo ta Kẹkẹ Maruwa ti wọn fi ṣe mi laanu danu, mi o mọ pe aṣiri maa tu - Azeez Saka


Gendekunrin kan, Azeez Saka ti jẹwọ nita gbangba wi pe ileeṣẹ eleto aabo So-Safe Corps nipinle Ogun wi pe ka loun mọ pe aṣiri maa pada tu sita ni, oun ki ba ti ma gbiyanju lati ta Kẹkẹ Maruwa ti wọn fi ṣe oun laanu danu.
 
AWIKONKO gbọ pe obinrin kan lo ra Kẹkẹ Maruwa, pẹlu erongba lati maa fi wa owo ounjẹ funra rẹ. Ko pẹ to ra Kẹkẹ Maruwa naa, lo pe Azeez Saka, ẹni ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Eko lati maa ba a fi ṣiṣẹ, ko si maa mu owo wa fun un lojoojumọ, iyẹn lẹyin to ba ti yọ owo tirẹ sapo.
 
Wọn ni Saka ko fi Kẹkẹ Maruwa naa ṣiṣẹ ju ọjọ meloo kan lọ, to fi na papa bora, ti wọn ko si rii mọ. Eyi lo jẹ ki obinrin to nii gba teṣan ọlọpaa, ati ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun, Sof-Safe Corps lọ lati fi to wọn leti.
 
Latigba naa la gbọ pe wọn ti n wa Saka kaakiri, ti wọn ko si rii.

Nigba ti aṣiri maa pada tu sita, wọn nibi ti gendekunrin meji kan, Abdulkadri Dauda ati Uthman Hudu ti n tu Kẹkẹ Maruwa ọhun, eyi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LSR602QG palẹ lọwọ palaba wọn ti segi, iyẹn lọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun ti a wa yii, ni nnkan bi agogo mẹjọ ku iṣẹju mẹrinla alẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Goro Yard, Atan, ijọba ibilẹ Ado Odo Ọta lawọn mejeeji yii n gbe, ibẹ si l'akara wọn ti tu s'epo. Lakooko ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo ni wọn ti jẹwọ wi pe Saka lo ta a fawọn lowo pọọku. 
 
Azeez Saka
 
Iwadii ti wọn ṣe lo mu ki ọwọ pada tẹ Saka, to si jẹwọ wi pe lotitọ loun ta Kẹkẹ Maruwa naa danu, koun too na papa bora, ati pe ẹgbẹrun mẹtalelogun naira lowo toun ta a fawọn to nilo rẹ.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Mọruf Yusuf to jẹ alukoro ileeṣẹ So-Safe Corps naa ṣalaye pe lotitọ ni, ati pe ẹni to ni Kẹkẹ Maruwa ọhun ti yọju, to si ti ṣalaye bi gbogbo ọrọ naa ṣe jẹ.
 
Yusuf sọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe kawọn ko awọn mẹtẹẹta lọ fawọn ọlọpaa ẹkun Atan, lati tẹsiwaju iwadii lori wọn, ki wọn le fi wọn jofin ọdaran.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI