Wàhálà nlá dé báwọn tó n yàgbẹ́ káàkiri orí àkìtàn, inú igbó àtàwọn ilé tí kò ní ṣálángá ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 30, 2022

Wàhálà nlá dé báwọn tó n yàgbẹ́ káàkiri orí àkìtàn, inú igbó àtàwọn ilé tí kò ní ṣálángá ní Kwara


Loju naa lati gbogun ti ajakalẹ arun Kọlẹra, ati oniruuru arun gbogbo, ijọba ipinlẹ Kwara lohun ti ṣetan lati gbogun ti gbogbo awọn to n yagbẹ kaakiri ori akitan, inu igbo, ati awọn ibi ti ko yẹ laaarin ilu.

Ijọba Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe awọn ti gbe igbimọ ti yoo ri si bi awọn iwa ibajẹ naa dide, lati gbogun ti wọn.

Ajọ to n ri sọrọ eto ayika nipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Environmental Protection Agency (KWEPA), ti bẹrẹ lati maa ti ojule de ojule, agbegbe de agbegbe lati mọ awọn ile ti ko ni ṣalanga.

Ohun ti a gbọ ni pe agbegbe Sango to wa nilu Ilọrin lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ti bẹrẹ iṣẹ imọtoto wọn, pẹlu erongba lati gbogun ti ajakalẹ arun gbogbo to n tan kaakiri ilu.

Ile ti ko din ni ogun la gbọ pe aṣiri wọn tu sita wi pe wọn ko ni ṣalanga ti wọn n yagbẹ si, to si jẹ pe inu igbo, ori akitan ati inu kọta ni wọn n da igbẹ si, paapaa lakooko ti ojo ba n rọ lọwọ.

Gbogbo awọn wọn yii ni wọn ti gba iwe ikilọ lati tete wa nnkan ṣe, iyẹn bi wọn ko ba fẹ ki ijọba ti ile wọn pa. Bakan naa awọn ile ti ṣalanga wọn ti kun, ti wọn ko si ko, eyi ti wọn lo n jẹ ki omi agbegbe naa bajẹ la gbọ pe awọn naa ti gbe iwe ikilọ.

Ṣaaju akoko yii ni alakoso ajọ naa, Alaaji Sa'ad Ayuba Dan-Musa ti sọ lori redio nipinlẹ Kwara wi pe agbegbe Sango lawọn ti fẹẹ bẹrẹ iṣẹ ayẹwo ọhun, latari awọn ẹsun ti wọn ti gba loriṣiriṣi nipa iwa buruku yii.

Olori ẹka kan nileeṣẹ to n ri si idalẹnu, Arabinrin Ọlawumi Taiwo Adedọtun, nigba toun naa n sọrọ ṣalaye pe awọn araalu maa n bẹru awọn Wole-Wole nigba kan, nitori ti wọn gbagbọ pe awọn gan-an ni agbofinro nipa imọtoto.

O wa gbawọn oṣiṣẹ wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn ma si ṣe gba abẹtẹlẹ kankan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI