Èyí làwọn Olúbàdàn mẹ́sàn-án tó bá Aláàfin, Ọba Adéyẹmí lórí ipò, tí wọ́n tún fi sílẹ̀ lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 5, 2022

Èyí làwọn Olúbàdàn mẹ́sàn-án tó bá Aláàfin, Ọba Adéyẹmí lórí ipò, tí wọ́n tún fi sílẹ̀ lọ


Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1970 ni Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta gba ade ati ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Alaafin Ọyọ kejidinlaadọta.
 
Ki Ọba Adeyẹmi kẹta too de ori itẹ, Ọba Salawu Akanni Aminu lo wa lori ipo gẹgẹ bi Olubadan tilẹ Ibadan. Ọdun 1965 ni Ọba Salawu gba ade rẹ, to si waja lọdun 1971, iyẹn ọdun kan lẹyin ti Ọba Adeyẹmi gba ade.
 
Ọdun 1971 naa ni wọn yan Olubadan miran, Ọba Shittu Akintọla Oyetunde keji, to si waja lọdun 1976. Ọdun marun-un ni Kabiyesi yii lo lori itẹ.

Ko ju bi oṣu meloo kan lọ ti Ọba Oyetunde keji waja ni wọn yan Ọba Gbadamọsi Akanbi Adebimpe, iyẹn lọdun 1976, to si jẹ pe ọdun kan ṣoṣo pere lo lo lori itẹ yii. Ọdun 1977 lo tẹri gbaṣọ.

Ọba Daniel Tayọ Akinbiyi, ni wọn fi jẹ lọdun 1977 naa, ṣugbọn toun lo marun-un lori itẹ gẹgẹ bi Olubadan. Ọdun 1982 lo tẹri gbaṣọ.

Ni kete ti Ọba Akinbiyi waja ni wọn ti yan Ọba Yesufu Oloyede Aṣanikẹ kin-in-ni, iyẹn lọdun 1982. Ọdun mejila gbako ni kabiyesi yii lo, ko to jẹ ipe awọn baba-nla rẹ lọdun 1994.

Ọba Emmanuel Adegboyega Ọperinde kin-in-ni gba ade tirẹ lọdun 1994 ti Ọba Aṣanikẹ kin-in-ni waja, toun si lo ọdun marun-un, ko to tẹri gbaṣọ lọdun 1999

Ko pẹ rara ti Ọba Ọpẹrinde kin-in-ni waja ni wọn yan Ọba Yunusa Ogundipẹ Arapaṣowu kin-in-ni, iyẹn lọdun 1999. Ọba Yunusa lo ọdun mẹjọ lori itẹ awọn baba-nla rẹ, ko to waja lọjọ 2007.

Ọba Samuel Odulana Odugade kin-in-ni lo gba ade lẹyin rẹ, iyẹn lọdun 2007. Ọdun mẹsan-an gbako ni kabiyesi yii lo, koun naa to pada sajule ọrun lọdọ awọn alalẹ lọdun 2016.

Lẹyin eyi ni wọn yan Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ kin-in-ni lọdun 2016 ti Ọba Odugade waja. Ọba Adetunji dagbere faye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, osu kin-in-ni, ọdun 2022 ti wa yii.
 
Gbogbo awọn ọba wọnyi ni wọn ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta. Ki Baba tubọ pẹ fun gbogbo ọmọ kaaro-o-jiire-bi laṣẹ awọn alalẹ, pẹlu atilẹyin Ọba adaniwaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI