Ọpẹ́ o, wọ́n ti tú ìyàwó ojú ọ̀nà tí wọ́n jígbé nílé pásítọ̀ sílẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 5, 2022

Ọpẹ́ o, wọ́n ti tú ìyàwó ojú ọ̀nà tí wọ́n jígbé nílé pásítọ̀ sílẹ̀


Bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ, sibẹ, awọn mọlẹbi ti sọ pe igbeyawo to yẹ ko waye laaarin Farmat Paul ti wọn jigbe ati ololufẹ rẹ yoo tẹsiwaju laipẹ.
 
Ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii la gbọ pe o yẹ ki igbeyawo naa waye, ṣugbọn ti wọn lawọn kan lọ ji iyawo gbe nile pasitọ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde ti igbeyawo ku wakati perete.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Ngyong, nijọba ibilẹ Bokkos, ipinlẹ Plateau niṣẹlẹ yii ti waye.
 
 
Ubah Gabriel Ogiba, to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si ni ohun to wa lọkan oun ni pe o ṣeeṣe ko jẹ pe obinrin naa lo fi ẹsẹ ara rẹ rin lọ sile ọkunrin, ko ma si jẹ pe ṣe ni wọn jiigbe, ṣugbọn to ni iwadii ṣi n lọ lọwọ.
 
Ogiba sọ pe bo tilẹ jẹ pe wọn ko wa fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti labẹ ofin, ṣugbọn to ni iyẹn ko sọ pe kawọn ma ṣe iwadii wọn, lati mọ ohun to ṣẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI