Ẹgbẹ awọn eleto ilera, Coalition of Health Sector Unions, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori idagbasoke to n mu ba eto ilera kaakiri ipinlẹ naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe lotitọ lo jẹ gomina araalu.
Wọn ni o ti fi han daju wi pe ọrọ araalu, ati igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ijọba ṣe pataki si i pupọ kọja nnkan ti ẹnikẹni le ronu nipa rẹ.
Eyi waye latari bi gomina ṣe bu ọwọ lu owo oṣu tuntun ti wọn ti ṣe atunṣe rẹ lati ọdun 2019, iyẹn Consolidated Health Salary Scale (CONHESS) fun gbogbo ẹka eto ilera nipinlẹ ọhun.
Nibẹ ni wọn tun ti lu AbdulRazaq lọgọ ẹnu lori bo ṣe n kọ ọsibitu kaakiri, eyi to n jẹ ki wọn wa ni ipo to ba ti igbalode mu.
No comments:
Post a Comment