SUBEB: Àwọn òṣìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sii gba lẹ́tà ìgbéga wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 27, 2022

SUBEB: Àwọn òṣìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sii gba lẹ́tà ìgbéga wọn


Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo awọn oṣiṣẹ to wa labẹ igbimọ akoso Kwara State Universal Basic Education Board wa bayii, lori bi wọn ti bẹrẹ sii gba lẹta igbega wọn.

A gbọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ laaarin ọdun 2017 ati 2018 kaakiri ipinlẹ naa ni wọn ti gba lẹta igbega wọn, ti wọn si n gbe oṣuba kare fun awọn alaṣẹ ati gomina wọn.

Alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Raheem Shehu Adaramaja lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Aminat Abiọla Atẹrẹ fi sita.

Bẹ o ba gbagbe, loṣu kẹjọ, ọdun to kọja ni ajọ naa ṣe idanwo ati ifọrọwanilẹnuwo fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ti yẹ fun igbega yii, eyi ti wọn ti ṣe akojọpọ rẹ laaarin ọdun 2017, 2018, 2019 ati 2020.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI