Ife ẹ̀yẹ àgbáyé: Nàìjíríà yóò kojú Ghana láràọ̀tọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 22, 2022

Ife ẹ̀yẹ àgbáyé: Nàìjíríà yóò kojú Ghana láràọ̀tọ̀


Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lagbaye, iyẹn Fédération Internationale de Football Association, FIFA ti sọ pe ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ni yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu ti orileede Ghana ninu ifigagbaga to kọgun si ife ẹyẹ agbaye, iyẹn African Qualifying Matches.

Ninu eto tuntun ti FIFA gbe jade laipẹ yii lo ti je ko di mimọ pe o ti di dandan bayii ki Nàìjíríà ati Ghánà koju ara wọn lati mọ ẹni ti yoo yege fun idije ife eye agbaye to fẹẹ waye lorileede Qatar lọdun yii 

Yatọ si Naijiria ati Ghana ti yoo koju ara won, Egypt yoo koju Senegal; Cameroon yoo koju Algeria; DR Congo yoo koju Morocco, nigba ti Mali ati Tunisia yoo fi agba han ara wọn.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii ni ifigagbaga naa yoo waye.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI