Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn kò wá ọmọ 'Yahoo' kankan, irọ́ nlá ni o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 23, 2022

Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn kò wá ọmọ 'Yahoo' kankan, irọ́ nlá ni o


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun loni, ọjọ Aiku tii ṣe Sannde ti sọ pe awọn ko gbe orukọ kankan sita wi pe awọn n wa, ati pe awọn ko wa ọmọ Yahoo-Yahoo kankan.
 
Laipẹ yii ni iroyin naa jade sita wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe awọn n wa awọn afurasi ọmọ Yahoo-Yahoo mọkanlelọgbọn kan, ti wọn si gbe orukọ gbogbo wọn sita.
 
Ninu iwe orukọ naa, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lati gbọ pe igbakeji ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ACP Yahaya Wakilu bu ọwọ lu.
 
Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ranṣẹ sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ wa lọwọ sọ pe irọ nla to jinna si otitọ ọrọ ni lẹta naa, ati pe gbogbo nnkan to wa ninu lẹta naa lo jẹ ayederu lati fi ṣi awọn araalu lọkan.
 
Wọn ni ko yẹ kawọn sọrọ jade lori lẹta ati akojọpọ orukọ  naa, ṣugbọn nitori awọn to le fẹ maa fi lẹta ọhun lu jibiti lo jẹ kawọn tete pariwo sita wi pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.
 
Siwaju sii ni wọn sọ pe ko si igbakeji ọga ọlọpaa kankan ti orukọ rẹ n jẹ Yahaya Wakilu, iyẹn to bu ọwọ lu lẹta naa, ati pe ko si igbakeji ọga ọlọpaa ti yoo lọ bairo pupa lati fi bu ọwọ lu iwe.

Bẹẹ ni wọn sọ pe ko nọmba ẹrọ ibanisọrọ to wa lori ayederu iwe naa lo jẹ ti ọga ọlọpaa kan to ti fẹyinti tipẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI