Ọjọ gbogbo ni t'ole, ọjọ kan ṣoṣo ti wọn pe ni t'olohun lo de ba ogbologbo adigunjale kan lagbegbe Atan Ọta, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta nipinlẹ Ogun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Kani kii ṣe pe awọn eleto aabo ipinlẹ Ogun, So-Safe Corps ko fọrọ ọhun falẹ rara ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe gbogbo awọn adigunjale naa lo maa raaye na papa bora, ki wọn si ma ri ẹnikankan mu balẹ ninu wọn.
AWIKONKO gbọ pe ileeṣẹ Flour Mill to wa lagbegbe Ararọmi, loju ọna Orita, opopona Ṣokoto, Atan Ọta, lawọn adigunjalẹ yii lọ ja lole lọjọ karundinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni nnkan bi agogo mẹwaa ku iṣeju mẹẹdọgbọn.
Wọn ni bi olobo naa ṣe tẹ awọn So-Safe lọwọ ni wọn ti sare gbera lọ sibẹ, ti wọn si doju kọ awọn adigunjale naa to to bii mẹjọ pẹlu nnkan ija oloro loriṣiriṣi.
Nibi ti wọn ti n fibọn dabira funra wọn, ni ọkan lara wọn ti fara gbọta, to si ṣubu lulẹ ku loju ẹsẹ. Eyi lo si jẹ kawọn yooku na papa bora, ti wọn ko si duro gbe awọn ẹru ti wọn wa jigbe.
Foonu itel kan, bata ẹsẹ meji ọtọọtọ, awọn ohun elo inu ile to n lo ina atawọn nnkan miran ni wọn gba lọwọ wọn, ki wọn to salọ.
Gbogbo awọn nnkan wọnyi la gbọ pe wọn ti fa le awọn ọlọpaa ẹkun Atan Ọta lọwọ, to fi mọ oku ọkan lara wọn.
No comments:
Post a Comment