Ìró lágbára àwọn ọ̀dọ́, àìsí ojúsàájú nínú ipò ló jẹ wá lógún - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 17, 2022

Ìró lágbára àwọn ọ̀dọ́, àìsí ojúsàájú nínú ipò ló jẹ wá lógún - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe iro lagbara awọn ọdọ, aisi ojusaaju ninu ipo pinpin laaarin ọkunrin ati obinrin lo jẹ ijọba oun logun, ohun si ni wọn n ṣiṣẹ le lori loorekoore.

Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa lakooko to n gba igbimọ ẹlẹni mẹta fẹgbẹ awọn ọdọ kan ti wọn pe ara wọn ni Nigerian Youth Parliament (NYP) lalejo nile gomina.

O ni fifi awọn ohinrin ti ipo to ga julọ wa lara ìpinnu wọn, ati lati maa ṣagbatẹru eto to ba ti nii ṣe pẹlu idagbasoke awọn ọdọ.

Awọn igbimọ naa ni Adefila Ifẹoluwa (Kwara South), Abubakar Sadiqq Buhari (Kwara North), ati Ibraheem Abdullateef (Kwara Central) to lewaju wọn.

Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti gbe oriyin fun wọn lori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe, to si ni gbogbo bo ṣe n lọ laaarin wọn loun n gbọ nipa idagbasoke ipinlẹ naa.

O wa jẹ ko di mimọ pe awọn fẹẹ di gbogbo alafo to wa laaarin ipinlẹ Kwara ati ẹgbẹ awọn ọdọ lorileede Naijiria, ki ibaṣepọ to dan mọnran le wa laaarin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI