Lẹ́yìn oṣù márùn-ún lẹ́wọ̀n, wàhálà tuntun débá Ìgbòho lọ́dún tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 4, 2022

Lẹ́yìn oṣù márùn-ún lẹ́wọ̀n, wàhálà tuntun débá Ìgbòho lọ́dún tuntun


Wahala ati idaamu nla lo tun ti deba Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho pẹlu bi ọkan gboogi lara awọn agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Pẹlumi Ọlajẹngbesi ṣe kọwe wi pe oun ko le tẹsiwaju mọ lati maa gbẹjọro fun olori ajijangbara fun ilẹ Yoruba naa.
 
Eyi waye latai wahala to bẹ silẹ laaarin oun ati awọn alati;ẹyin Sunday Igboho, ẹni ọdun mọkandinlaadọta.
 
Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii la gbọ pe Ọlajẹngbesi kọwe wi pe oun ko lẹ ba Igboho ṣiṣẹ mọ gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ, nitori pe oun kii ṣe ajijangbara fun ilẹ Yoruba.
 
Lara awọn idi pataki ti wọn ni Ọlajẹngbesi fi kọwe fipo rẹ silẹ ni bi Ọjọgbọn Banji Akintoye ṣe sọ pe ko nii si eto idibo kankan lọdun yii nipinlẹ Ekiti ati Ọṣun.

Ninu ọrọ Ọjọgbọn Akintoye fun ọdun yii lo ti sọ pe gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un, wi pe eto idibo kankan ko nii waye lọdun yii, ati pe eto idibo akọkọ ti yoo ba waye ni yoo jẹ nigba ti ilẹ Yoruba ba ti da duro, ti wọn si ti gba orileede ti wọn.

Ọlajẹngbesi nigba to n tako ọrọ sọ pe Akintoye ko sọrọ lorukọ Igboho ati gbogbo ọmọ Yoruba, nitori pe ẹtọ awọn eeyan ni lati dibo yan ẹni ti wọn ba n fẹ.

Bi ọrọ yii ṣe tẹ Akintoye lọwọ lo ti pariwo sita wi pe Ọlajẹngbesi ti gbabọdi, ati pe kii ṣe ọrọ ti Igboho le sọ jade ni Ọlajẹngbesi sọ yẹn, to si ni ṣe lo n wa gbogbo ọna lati wa ojurere Aarẹ Muhammadu Buhari.
 
Eyi lo jẹ ki Ọlanjẹngbesi fibinu kọwe wi pe oun ko le tẹsiwaju lati maa gbẹjọro fun Igboho ati gbogbo awọn to n ja fun ominira ilẹ Yoruba mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI