Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree ti awọn Asọtẹlẹ gbajugbaja Wolii ni, Wolii Elijah Ayọdele yoo maa wa si imuṣẹ, ti awọn eeyan si n jẹrii si i, eyi to tun ṣẹṣẹ wa si imuṣẹ yii n jẹ kayeefi nitori pe ọsẹ meji to ju asọtẹlẹ naa sita lo fidi mulẹ.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja yii ni Wolii Ayọdele gbe asọtẹlẹ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun yii jade, eyi ti awa naa si kọ ọ sita.
Ninu awọn asọtẹlẹ naa ni Wolii Ayọdele to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church to wa nilu Igando, ipinlẹ Eko ti sọ pe wahala nla yoo deba Oloye Sunday Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho, ati pe bi ko ba ṣọra, wahala yoo bẹ sile laaarin oun pẹlu awọn agbẹjọro rẹ.
Wolii Ayọdele sọ pe Sunday Igboho nilo lati paarọ agbẹjọro rẹ, to ba fẹẹ ja ajaye, ko si bọ kuro ninu ọgba ẹwọn to wa lati oṣu keje, ọdun 2021.
Asọtẹlẹ yii ni AWIKONKO gbe jade lọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila naa.
Yatọ si eyi, Wolii Ayọdele tun mẹnuba iku Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji to waja lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
No comments:
Post a Comment