Lọ́jọ́ tí AbdulRazaq gba ààmì ẹ̀yẹ l'Abuja, àwọn obìnrin sọ̀rọ̀, ilẹ̀ kún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 23, 2022

Lọ́jọ́ tí AbdulRazaq gba ààmì ẹ̀yẹ l'Abuja, àwọn obìnrin sọ̀rọ̀, ilẹ̀ kún


Ọjọ manigbagbe nla lọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni ọdun 2022 jẹ ninu igbesi aye gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman Abdulrazaq pẹlu bi agbarijọ ẹgbẹ awọn obinrin lẹgbẹ oṣelu All Progressives COngress, APC kaakiri orileede Naijiria ṣe pawọpọ lati gbe aami ẹyẹ nla fun un.
 
Kii ṣe pe boya awọn obinrin wọnyi ti olu ile ẹgbẹ wọn wa nilu Abuja deedee pinnu lati fun Gomina AbdulRazaq ni awọọdu nla yii, bi ko ṣe bo ṣe fi ipo nla da awọn obinrin lọla ninu iṣakoso rẹ, ti ko si yọ awọn obinrin sẹyin ninu awọn ipo pataki igbimọ iṣakoso ijọba rẹ.
 
Yatọ si pe AbdulRazaq fi awọn obinrin sipo pataki ninu ijọba rẹ, bẹẹ lo tun bu ọwọ lu awọn abadofin to nii ṣe pẹlu ipo tawọn obinrin gbọdọ di mu.
 
Nigba to n sọrọ, aṣoju awọn obinrin igbimọ iṣakoso eto ipade gbogboogbo lẹgbẹ oṣelu APC, Ọnọrebu Stella Okotete gbe oṣuba kare nla fun AbdulRazaq lori bo ṣe yan awọn obinrin sawọn ipo pataki.
 
Bẹẹ lo tun gba awọn gomina kaakiri lamọran lati tẹle ilana ati ipasẹ gomina AbdulRazaq.
 
Lara awọn to wa nibi eto naa ni igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo; igbakeji aarẹ orileede Liberia, Ọmọwe Jewel Taylor; Sẹnetọ Yahya Oloriẹgbẹ (Kwara Central); Sẹnetọ Lọla Ashiru (South) ati Sẹnetọ Sadiq Umar (North).
 
Awọn miran ni awọn aṣoju-ṣofin ti wọn jẹ obinrin kaakiri Naijiria; awọn iyawo gomina; Minisita fọrọ awọn obinrin, Paulen Tallen; atawọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI