Nítorí ikú alága wọn, AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí ẹgbẹ́ CAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 8, 2022

Nítorí ikú alága wọn, AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí ẹgbẹ́ CAN


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe abẹwo ibanikẹdun si ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN, ẹka ti ipinlẹ Kwara lori iku alaga wọn, Rẹfurẹndi Paul Ọlawoore.

Rẹfurẹndi Ọlawoore lo jade laye laipẹ yii, ti iroyin iku naa si mi gbogbo ilu, paapaa orileede Naijiria titi.

Nigba to n gba ẹnu gomina sọrọ nibi abẹwo ibanikẹdun ọhun, igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi sọ pe adanu nla niku agba ẹlẹsin Kristẹni naa jẹ fun gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Kwara.

O ni asiko ree ti onikaluku yoo tun ero rẹ pa, nitori pe awaye ma lọ kan ko si, ati pe gbogbo eeyan lo dagbada iku.

Alabi sọ pe asiko ti onikaluku ba de ebute ibudokọ ni yoo sọkalẹ, nitori pe Ọlawoore ti de ebute tirẹ lo jẹ ko gba ọrun lọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI