Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ti lọ sọ ipinnu oun fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati jade du ipo Aarẹ lọdun 2023 to n bọ yii.
Tinubu lo sọrọ yii wita lọjọ Aje, Mọnde ana, lakooko nilu Abuja, lakooko to lọ ṣabẹwo si Aarẹ Buhari nile agbara orileede yii, iyẹn Aso-Rock.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Tinubu sọ pe awọn ọmọ Naijiria nikan lo ku toun yoo sọ erongba oun fun lati jade du ipo Aarẹ, ṣugbọn toun ti lọ fi to Buhari leti, ko le maa gbaradi.
O nidi toun ko tii ṣe sọ erongba toun sita ni pe oun ṣi n fimu finlẹ, oun ṣi n kan si awọn agbaagba atawọn alẹnulọrọ lori ipinnu naa, ati pe oun o ni wahala kankan pẹlu iyẹn.
Siwaju sii lo sọ pe gbogbo ohun tawọn ọmọ Naijiria n fẹ lati gbọ ni wọn maa gbọ lẹnu oun laipẹ, nitori pe Buhari ko sọ foun lati ma ṣe jade du ipo naa nigba toun lọ sọ fun un.
No comments:
Post a Comment