Nítorí ikú èèyàn mẹ́rin, àwọn aráàlú dáná sun mọ́tò kọ́sítọ̀ọ̀mù méjì lẹ́ẹ̀kan náà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 4, 2022

Nítorí ikú èèyàn mẹ́rin, àwọn aráàlú dáná sun mọ́tò kọ́sítọ̀ọ̀mù méjì lẹ́ẹ̀kan náà


Ṣe ni ọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti awọn araalu fa ibinu yọ, ti wọn si dana sun mọto awọn ẹṣọ aṣọbade to kọsitọọmu, iyẹn Nigerian Customs Service, nitori iku awọn mẹrin kan.
 
AWIKONKO gbọ pe awọn ẹṣọ aṣọbode yii ni wọn lọwọ si bi ijamba mọto ṣe waye lopopona marosẹ Ṣokoto si Illela, eyi to gba ẹmi awọn ti ko din ni mẹrin lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Yatọ si awọn mẹrin to jade laye nibi ijamba yii, a gbọ pe awọn mẹfa miran farapa yannayanna kọja sisọ, to si jẹ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni wọn wa titi dakooko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
 
Awọn to gbe iroyin yii si wa leti sọ pe ibudo tawọn ẹṣọ aṣọbode ti n yẹ awọn ọkọ to n kọja lọ wo lagbegbe Asara ni ijamba naa ti waye, eyi ti mọto Toyota Avensis meji ati Golf kan ti kọlu ara wọn lojiji.
 
Bi awọn mẹrin naa ṣe ku, ti awọn miran si tun farapa lo mu kawọn araalu to wa nitosi sare lọ sibẹ, ti wọn si dana sun mọto meji to jẹ ti kọsitọọmu.
 
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ọkan lara awọn awakọ mọto to nijamba yii lo fẹẹ salọ fun awọn ẹṣọ aṣọbode nitori irẹsi to gbe ati ororo isebẹ to gbe dani
 
Wọn nibi ti awọn kọsitọọmu yii ti n da awakọ naa duro, ṣugbọn ti ko dahun, lo jẹ ko sọ ijanu rẹ nu, to si lọ kọlu awọn mọto to n bọ lẹyin rẹ.
 
Loju ẹsẹ nibẹ ni wọn sọ pe awọn mẹrin ti je alaisi, ti awọn mẹfa si farapa yannayanna. Awọn to farapa ọhun la gbọ pe wọn ko lọ si ọsibitu Gwandabawa fun itọju.
 
Ni kete ti wọn lawọn ti iṣẹlẹ yii ko dun mọ ninu ti debẹ, ni wọn ti dana sun mọto meji tawọn aṣọbode yii gbe sẹgbẹ kan, ti wọn si rii pe o jona di eeru, ko to di pe wọn kuro nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI